Yoruba Bible

SAKARAYA
Chapter 1 of 14
left-arrow Chapter - 1 right-arrow
Verse 1

LI oṣù kẹjọ, li ọdun keji Dariusi, li ọ̀rọ Oluwa tọ̀ Sekariah wá, ọmọ Berekiah ọmọ Iddo woli, pe,

Verse 2

Oluwa ti binu pupọ̀ si awọn baba nyin.

Verse 3

Nitorina iwọ wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; Oluwa awọn ọmọ-ogun wipe, Ẹ yipadà si mi, emi o si yipadà si nyin, ni Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.

Verse 4

Ẹ má dàbi awọn baba nyin, awọn ti awọn woli iṣãju ti ké si wipe, Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; Ẹ yipadà nisisiyi kuro li ọ̀na buburu nyin, ati kuro ninu ìwa-buburu nyin: ṣugbọn nwọn kò gbọ́, bẹ̃ni nwọn kò fetisi ti emi, ni Oluwa wi.

Verse 5

Awọn baba nyin, nibo ni nwọn wà? ati awọn woli, nwọn ha wà titi aiye?

Verse 6

Ṣugbọn ọ̀rọ mi ati ilàna mi, ti mo pa li aṣẹ fun awọn iranṣẹ mi woli, nwọn kò ha fi mu awọn baba nyin? nwọn si padà nwọn wipe, Gẹgẹ bi Oluwa awọn ọmọ-ogun ti rò lati ṣe si wa, gẹgẹ bi ọ̀na wa, ati gẹgẹ bi iṣe wa, bẹ̃ni o ti ṣe si wa.

Verse 7

Li ọjọ kẹrinlelogun oṣù kọkanla, ti iṣe oṣù Sebati, li ọdun keji Dariusi, li ọ̀rọ Oluwa tọ̀ Sekariah, ọmọ Berekiah ọmọ Iddo woli wá, pe,

Verse 8

Mo ri li oru, si wò o, ọkunrin kan ngun ẹṣin pupa kan, on si duro lãrin awọn igi mirtili ti o wà ni ibi õji; lẹhìn rẹ̀ si li ẹṣin pupa, adíkalà, ati funfun gbe wà.

Verse 9

Nigbana ni mo wipe, Kini wọnyi oluwa mi? Angeli ti mba mi sọ̀rọ si wi fun mi pe, emi o fi ohun ti wọnyi jẹ hàn ọ.

Verse 10

Ọkunrin ti o duro lãrin awọn igi mirtili si dahùn o si wipe, Wọnyi li awọn ti Oluwa ti rán lati ma rìn sokè sodò li aiye.

Verse 11

Nwọn si da angeli Oluwa ti o duro lãrin awọn igi mirtili na lohùn pe, Awa ti rìn sokè sodò já aiye, si kiyesi i, gbogbo aiye wà ni isimi, o si duro jẹ.

Verse 12

Nigbana ni angeli Oluwa na dahùn o si wipe, Oluwa awọn ọmọ-ogun, yio ti pẹ to ti iwọ kì yio fi ṣãnu fun Jerusalemu, ati fun awọn ilu-nla Juda, ti iwọ ti binu si li ãdọrin ọdun wọnyi?

Verse 13

Oluwa si fi ọ̀rọ rere ati ọ̀rọ itùnu da angeli ti mba mi sọ̀rọ lohùn.

Verse 14

Angeli ti mba mi sọ̀rọ si wi fun mi pe, Iwọ kigbe wipe, Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; emi nfi ijowu nla jowu fun Jerusalemu ati fun Sioni.

Verse 15

Emi si binu pupọ̀pupọ̀ si awọn orilẹ-ède ti o gbe jẹ: nitoripe emi ti binu diẹ, nwọn si ti kún buburu na lọwọ.

Verse 16

Nitorina bayi li Oluwa wi; mo padà tọ̀ Jerusalemu wá pẹlu ãnu; Oluwa awọn ọmọ-ogun wipe, a o kọ ile mi sinu rẹ̀, a o si ta okùn kan jade sori Jerusalemu.

Verse 17

Ma ke sibẹ̀ pe, Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; A o ma fi ire kún ilu-nla mi sibẹ̀; Oluwa yio si ma tù Sioni ninu sibẹ̀, yio si yàn Jerusalemu sibẹ̀.

Verse 18

Mo si gbe oju mi soke, mo si ri, si kiyesi i, iwo mẹrin.

Verse 19

Mo si sọ fun angeli ti o ba mi sọ̀rọ pe, Kini wọnyi? O si da mi lohùn pe, Awọn wọnyi ni iwo ti o ti tú Juda, Israeli, ati Jerusalemu ka.

Verse 20

Oluwa si fi gbẹnàgbẹnà mẹrin kan hàn mi.

Verse 21

Nigbana ni mo wipe, kini awọn wọnyi wá ṣe? O si sọ wipe, Awọn wọnyi ni iwo ti o ti tú Juda ka, tobẹ̃ ti ẹnikẹni kò fi gbe ori rẹ̀ soke? ṣugbọn awọn wọnyi wá lati dẹruba wọn, lati le iwo awọn orilẹ-ède jade, ti nwọn gbe iwo wọn sori ilẹ Juda lati tu u ka.

Chapter -
1