mother

Orukọ Oluwa, ile-iṣọ agbara ni: Olododo sá wọ inu rẹ̀, o si là.

ÌWÉ ÒWE 18 : 10

Oju daradara li ẹ̀tan, ẹwà si jasi asan: ṣugbọn obinrin ti o bẹ̀ru Oluwa, on ni ki a fi iyìn fun.

ÌWÉ ÒWE 31 : 30

O fi ọgbọ́n yà ẹnu rẹ̀; ati li ahọn rẹ̀ li ofin iṣeun.

ÌWÉ ÒWE 31 : 26

Tani yio ri obinrin oniwà rere? nitoriti iye rẹ̀ kọja iyùn.

ÌWÉ ÒWE 31 : 10

Ọmọ mi, gbọ́ ẹkọ́ baba rẹ, ki iwọ ki o má si kọ̀ ofin iya rẹ silẹ:

ÌWÉ ÒWE 1 : 8

On a si dide nigbati ilẹ kò ti imọ́, a si fi onjẹ fun enia ile rẹ̀, ati iṣẹ õjọ fun awọn ọmọbinrin rẹ̀.

ÌWÉ ÒWE 31 : 15

Agbara ati iyìn li aṣọ rẹ̀; on o si yọ̀ si ọjọ ti mbọ.

ÌWÉ ÒWE 31 : 25

Awọn ọmọ rẹ̀ dide, nwọn si pè e li alabukúnfun, ati bãle rẹ̀ pẹlu, on si fi iyìn fun u.

ÌWÉ ÒWE 31 : 28

Fi fun u ninu eso-iṣẹ ọwọ rẹ̀; jẹ ki iṣẹ ọwọ ara rẹ̀ ki o si yìn i li ẹnu-bodè.

ÌWÉ ÒWE 31 : 31

Tani yio ri obinrin oniwà rere? nitoriti iye rẹ̀ kọja iyùn.

ÌWÉ ÒWE 31 : 10